Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn fi àsìkò ọdún Egúngún tó ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Ìbàdàn gbàdúrà fún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

0 1,636

Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Olalekan Balogun, Alli Okunmade II ti fi àsìkò ọdún Egúngún tó tí bẹ̀rẹ̀ ní igun mẹrẹrin ìlú Ìbàdàn gbàdúrà fún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

 

Ọdún Egúngún eléyìí tó má n wáyé lọdọọdun jake jado ìlú Ìbàdàn lo gbéra sọ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtadinlogbon oṣù kẹfà ọdún yìí tí àwọn Egúngún lolokan-ojokan pẹ̀lú àwọn àtẹ̀lé wọn fi ìlù àti ijó dá Olúbàdàn àti àwọn Baale pẹ̀lú gbogbo ìgbìmọ̀ Olúbàdàn lára yá ní gbangba Aliiwo ní ìlú Ìbàdàn, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ẹkùn gúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Díẹ Lára àwọn Egúngún tó wà láti wá yẹ Kábíyèsí Olúbàdàn sí ní Eégún Gbebolaja ti Ojaagbo eléyìí tí ìtàn fi ìdí rẹẹ̀ múlẹ̀ wípé ko gbọdọ̀ fi ẹsẹ rin de iwaju Kábíyèsí bikose ki o ma rababa ni ile titi yoo fi de iwaju ọba ki àjálù ko má baa sẹlẹ, ati pe ki iru Ọba bee le ri ọdún Egúngún mìíràn.

Abiola Olowe
Ibadan

Leave A Reply

Your email address will not be published.