Take a fresh look at your lifestyle.

ILÉ ẸJỌ́ GÍGA FI AFURASÍ ONÍJÌBÌTÌ ORÍ Ẹ̀RỌ AYÉLUJÁRA SÍ ÀTÌMỌ́LÉ.

0 351

Àjọ tó ń gbogun ti ìwà ibaje àti ṣíṣe ọwọ́ ìlú kúmo-kùmo, EFCC, ẹkùn ti Ìbàdàn ti gbé Babawale Daniel Olayinka lọ sí ilé ẹjọ níwájú Onídàájọ Uche Agomoh ti Ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ tí ó joko nílùú Ìbàdàn tí í ṣe olu ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ẹkùn gúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ẹsun márùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ to da lori jibiti ori ero ayelujara ni Àjọ EFCC fi kan Babawale Daniel ni ọjọ Ketalelogun osu kefa odun yi, (23/06/2022) ninu eyi ti afurasi ohun so wipe oun ko jebi àwọn esun ti wọn fi kan an.

Agbẹjọro fun eniti wọn fi esun kan, Mukhtar Aderogba ati Nurullah Musa wa bebe ki ile ejo gba beeli re, eleyi ti Onidajo Agomoh fi owo si fun won lati lo san owo to to aabo milioni naira (N500,000.00) ati oniduro meji, ti awon mejeeji si gbodo ni eri idaniloju pe won ni ile ni agbegbe ile ejo giga, ti okan lara awon oniduro ohun si gbodo fi owo to to egberun lona ogorun (N100,000.00) naira sile lodo akowe ile ejo.

Ile ẹjọ wa fi afurasi ohun si atimole titi awon agbejoro re yoo fi pari eto lati ri oniduro re, ti Ile ejo si sun igbejo si ojo karun osu kewa odun yi (05/10/2022).

Abiola Olowe
Ibadan

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button