Take a fresh look at your lifestyle.

Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn kìlọ̀ fún àwọn eégún ṣáájú ọdún Egúngún tó ń bọ̀.

0 608

Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Olalekan Balogun, Alli-Okunmade II ti tẹ̀ẹ́ mọ́ gbogbo àwọn tí yóò kópa nínú ọdún Egúngún tí ọdún yìí, eléyìí tí yóò bèrè ní ọjọ́ Ajé (27/06/2022) láti yàgò fún ìwà ipanle eléyìí tó sábà máa ń wáyé.

Ọba Balogun ló fi ìkìlọ yìí síta nínú atẹjade kan láti ọwọ́ akọ̀wẹ́ ìròyìn rẹẹ̀, Oladele Ogunsola ṣáájú ọdún ohun nínú èyí tí wọn yóò ṣe àìsùn rẹ ní ọjọ́ Àìkú (26/06/2022) ní agbo-ilé gbogbo àwọn tó ń ṣe ọdún Egúngún jákè jádò ìlú Ìbàdàn.

Àtẹ̀jade ọ̀hún tún jẹ kí ó di mímọ̀ pé ajọdun ọdún Egúngún ohun yóò bèrè ní Ààfin Aliiwo Olúbàdàn, ní ìlú Ìbàdàn tí í ṣe olú ìlú Ìpínlè Ọ̀yọ́ ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nígbàtí àwọn Àgbà Egúngún t Atipako yó le waju wọn yóò máa fi ìlù àti ijó dá àwọn igbimọ Olúbàdàn lára yá, tí wọn yóò si gbàdúrà sí àwọn Alale láti jẹ́kí àlàáfíà jọba ní ìlú Ìbàdàn.

Nígbà tí Olúbàdàn gbàdúrà fún àlàáfíà àti ifọkanbalẹ fún gbogbo ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn, O fi asiko ohun sọ fún àwọn agbofinro láti se isẹ wọn bi i se lásìkò ọdún Egúngún náà.

Abiola Olowe
Ibadan

Leave A Reply

Your email address will not be published.