Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rọ àwọn ọlọ́kadà láti gba nọ́mbà ìdánimọ̀ sí ọ̀kadà wọn

0 377

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti sọ́ di mímọ̀ pé ètò tí nlọ láti bẹrẹ ìforúkọsílẹ àti pínpín nọmba ìdánimọ̀ fún gbogbo ẹni tí ó n fi alupupu “okada” ṣe Ajé ìgboro ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Kọmísánà fún Ètò Ìṣúná àti Ìṣirò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Musibau Babatunde ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tí o n se ìpàdé pelu awon olori egbe olokada ti ko din ni Ọgọrun ni ilu Ìbàdàn ti i se olu ilu Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Musibau Babatunde jẹ́ kí ó yé àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn wípé, ètò iforukosile ati pinpin nomba idanimo yìí ki ṣe láti d’eye si enikeni ṣugbọn o jẹ́ okan lara ona ti iforukosile lati da gbogbo olugbe ìpínlè Ọ̀yọ́ mọ́, eléyìí ti ijọba gun le yóò fi kesejari fún Ètò ààbò tó gbópọn.

Bákan náà ni Kọ̀mísánà fún Ìròyìn, Àṣà àti Ìrìn-àjò Afẹ́ ní ìpínlè Ọ̀yọ́, ọ̀mọ̀wé Wasiu Olatubosun jẹ́ kí ó yé àwọn olórí ẹgbẹ́ olokada ohun pe iforukosile yii yoo mu ki ijoba le mo irufe olokada to ba fe wole lati awon ìpínlẹ̀ míìràn si ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lati dekun iru eni be e.

 

Abiola Olowe

Ibadan

Leave A Reply

Your email address will not be published.