Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbìmọ̀ Ọmọ bíbí Ilẹ̀ Ìbàdàn ti bẹ̀rẹ̀ ètò láti yọ ọwọ́ ìjọba tàbí òṣèlú kúrò nínú jíjẹ oyè àti Ọba ní ìlú Ìbàdàn.

0 422

Ìgbìmọ̀ Ọmọ bíbí Ilẹ̀ Ìbàdàn ( Central Council of Ibadan Indigenes) ti jẹ́ kí ó di mimọ̀ pé, òun ti bẹ̀rẹ̀ ètò láti ṣe atunto eléyìí tí yóò yọ ọwọ́ kilanko ìjọba tàbí òṣèlú kúrò nínú jíjẹ oyè àti Ọba ní ìlú Ìbàdàn ní ọ̀nà láti mú iyì àti ẹ̀yẹ dé ba a.

Ẹni tí ó ti fi ìgbà kan rilí jẹ́ Akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, tí ó tún jẹ Maye Balógun ìlú Ìbàdàn, Olóyè Sarafadeen Alli ló sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi ètò tí Ẹgbẹ́ Akọ̀rọ̀yìn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ (Correspondents’ Chapel of Oyo NUJ) ṣe àgbékalẹ̀ rẹ láti ye Kábíyèsí Olúbàdàn ilé Ìbàdàn, Ọba Olalekan Balogun, Ali-Okunmade II si. Ètò tó wáyé ní gbọ̀gán Dapo Aderogba nínú ọgbà NUJ tó wà ní agbègbè Iyaganku ní ìlú Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lóri àkòrí idanileko ohùn: Ìbàdàn Lana, Loni at Lola” (Ibadan Yesterday, Today and Tomorrow), Olóyè Sarafadeen Alli jẹ́ kí ó yé gbogbo awọn tó péjú pe, Ilé Ìbàdàn koni dekun láti máa ṣe gbogbo ohun tó wà ní ikawọ rẹ ẹ̀ láti máṣe fàyè gba òṣèlú tàbí ìjọba nínú Ìlànà ifinijoye ní ìlú Ìbàdàn.

Abiola Olowe
Ibadan

Leave A Reply

Your email address will not be published.