Take a fresh look at your lifestyle.

Olúbàdàn ilé Ìbàdàn, gba àwọn olóyè tó gba ìgbéga níyànjú.

0 441

Olúbàdàn ilé Ìbàdàn, Ọba Lekan Balogun gba àwọn olóyè àgbà tó ṣẹ̀ gba ìgbéga níyànjú.Olúbàdàn ilé Ìbàdàn, Ọba Lekan Balogun, Alli Okunmade II ti gba àwọn olóyè àgbà márùn tí wọ́n gba ìgbéga láti ìpele kan sí òmíràn níyànjú láti rí ara wọn gẹ́gẹ́ bi alákòóso ààbò ní agbègbè wọn.

Ọba Lekan Balogun, ẹni tí ọ̀tún Balógun Ilélè Ìbàdàn, Àgbà Oyè Tajudeen Ajibola sojú rẹẹ̀ ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ fún àwọn olóyè àgbà márùn òhún láti fi ìgbéga òhún mú ààbò, àlàáfíà àti ìdùnnú bá àwọn èèyàn agbègbè wọn. Kí wọ́n ríi dájú pé wọn kò fààyè gba àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí, yálà Fulani tàbí ẹnikẹ́ni tó le dàa omi àlàáfíà agbègbè wọn rú.

Àwọn olóyè tí wọ́n gba ìgbéga òhún ni: Àgbà Oyè (Senator) Rasidi Adewolu Ladoja, ẹni tí wọn gbé ga láti ipò “òsì Olúbàdàn” sí ipò “ọ̀tún Olúbàdàn; Àgbà Oyè Eddy Oyewole, láti ipò “Asípa Olúbàdàn” sí ipò “Òsì Olúbàdàn”; Àgbà Oyè Abiodun Kola Daisi láti ipò “Ẹkẹrin Olúbàdàn” sí ipò “Asípa Olúbàdàn”; Àgbà Oyè Hamidu Ajibade láti ipò “Ẹkarun Olúbàdàn” sí ipò “Ẹkẹrin Olúbàdàn” àti Àgbà Oyè Adebayo Akande, láti ipò “Abese Olúbàdàn” sí ipò “Ẹkarun Olúbàdàn” Ilé Ìbàdàn.

Lára àwọn tó péjú síbẹ̀ ni: Ìyàwó Àgbà Oyè Rasidi Adewolu Ladoja, Olóyè Mutiat Ladoja; Ìyàwó Àgbà Oyè Adebayo Akande, Olóyè Onikepo Akande; Amòfin Teslim Folarin àti àwọn ẹ̀ẹ̀kàn miran.

Abiola Olowe
Ibadan

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button