Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti sọ́ di mímọ̀ wípé òun ò ní ye Ìlànà àń f’obá jẹ tò ti wà ní àkọsílẹ wò nígbà tí àsìkò bá tó láti yan ẹni tí yóò jẹ Aláàfin.
Gómìnà Seyi Makinde ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ lásìkò tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Ọba alayé, aláàfín ti ìlú Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Adeyemi 111 tó wàjà ní Ọjọ kejìlélógún oṣù Kẹrin, ọdún 2022. (22/04/2022).
Ayẹyẹ ìkẹyìn ọ̀hún ló wáyé ní agbègbè Oliveth Baptist High School tó wà ní ìlú Ọ̀yọ́ ní ẹkùn gúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tí àwọn ládé-ládé àti lóyè-lóyè pẹ̀lú àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ olóṣèlú Jákè-jádò Ilẹ̀ kaaro-ojiire ti péjú láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Ọba alayé tó wàjà ní Ọjọ kejìlélógún oṣù Kẹrin, ọdún 2022.
Lára àwọn tó péjú ni:
Olúbàdàn tí ilẹ̀ Ìbàdàn Ọba Mohood Lekan Balogun, Alli Okunmade 11, ẹni tí Òsì Olúbàdàn Àgbà Oyè Eddy Oyewole sojú fún; Olúwo ìlú Ìwó Ọba Abdulrasheed Akanbi; Onjeru ti Ijeru Oba Sunday Oyediran; Ọmọọba Olagunsoye Oyinlola (Gomina ipinle Osun tẹ́lẹ̀ rí); Ààrẹ Ọna Kakanfo ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams; Ààrẹ ẹgbẹ́ ọmọ lẹyìn Krístì (CAN) Revd Samson Ayokunle; Imamu Agba ilu Oyo Alhaji Abduganiy Ajokidero; Bishop Ayo Ladigbolu, tí i ṣe olugbalejo àti àwọn otookulu míìràn láwùjọ.
Abiola Olowe
Ibadan
Leave a Reply