Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ bíbí àti olùgbé ìpínlè Ọ̀yọ́ yóò tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ ní kété tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC bá jáwé olúborí nínú ìdìbò ọdún 2023-Olóyè Adebayo Adelabu

0 220

Olóyè Adebayo Adelabu tí oh jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó fẹ́ díje du ipò gómìná ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lábẹ́ àsìà ẹgbẹ́ òṣèlú APC nínú ìdìbò ọdún tó ńbọ̀ ló sọpé gbogbo ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ bíbí àti olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni yóò tè wọ́n lọ́wọ́ ní kété tí ìjọba bá padà sọ́wọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC nínú ìdìbò ọdún 2023 lásìkò tí ó ń fi èróngbà rẹẹ̀ hàn fún gbogbo ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti díje du ipò gómìná nínú ètò ìdìbò ọdún 2023.

Ètò tí ó wáyé ní gbangba Ilé ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó wà ní agbègbè Òkè-Àdó ní ìlú Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ẹkùn gúsù iwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, níbi tí Olóyè Adelabu ti rọ gbogbo ọmọ bíbí àti olùgbé ìpínlè Ọ̀yọ́ ní’lé àti lóko láti fi ìbò wọn tí í ṣe agbára wọn láti gbé wọlé gégébi gómìná ìpínlè Ọ̀yọ́ nínú ìdìbò ọdún tó ńbọ̀.

Lára àwọn tó péjú síbẹ̀ ni igbákejì gómìná ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀rí, Olóyè Moses Alake Adeyemo; Olórí òṣìṣẹ́ lábẹ́ iséjọ̀ba Senator Rashid Ladoja, Olóyè Sarafadeen Ali; Olóyè Akinade Fijabi; Abẹnugan Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀rí, Rt. Hon. Gunju Ojo; Senator Ayoade Adeseun, àti àwọn èèkàn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC jákè jádò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

 

Abiola Olowe

Ìbàdàn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button