Ààrẹ Muhammadu Buhari ti balè sí Abu Dhabi, olú ìlú United Arab Emirates láti lọ jíròrò pẹ̀lú ààrẹ tuntun ti orílẹ̀-èdè UAE.
Aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìlú UAE, Mohammed Buba àti díẹ̀ lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba orílẹ̀-èdè UAE ló gba Ààrẹ Buhari tí ó gbéra ní alẹ́ Ọjọ́bọ lálejò.
À ń retí kí olórí orílẹ̀-èdè Nàíjíríà àti UAE sọ̀rọ̀ lóri bí wọn yóò ṣe mú kí àjọsepọ̀ láàrín àẁọn orílẹ̀-èdè méjèjì dánmọ́rán si.
Ọláyinká Akíntọ́lá
Leave a Reply