Take a fresh look at your lifestyle.

NMA banújẹ́ Lórí Ètò Ìtọ́jú Ìlera Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tó mẹ́hẹ

Eyitayọ Fauziat Oyeyunji

0 187

Ẹgbẹ́ Ìṣòògùn Nàìjíríà (NMA),ti banújẹ́ lórí Ètò Ìtọ́jú Ìlera Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tó mẹ́hẹ ní Nàìjíríà,ó sọ pé ó  léwu fún ìlera ọmọnìyàn.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Dokita Innocent Ujah, sọ ni Port Harcourt, Ipinlẹ Rivers, nibi ibaraẹnisọrọ pẹlu awọn oniroyin kan lori apejọ gbogboo ọlọdọọdun ati ipade awọn aṣoju ẹlẹẹkejile-lọgọta ti yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹẹdogun,oṣu karun un  si ọjọ kọkanle-logun ni Ipinlẹ Rivers.

Gẹgẹ bi o ti sọ, eto ilera alakọbẹrẹ ti fori ṣọnpọn,ti awọn oludari orilẹ-ede si yẹ ki wọn wa ọna abayọ.

NMA wa bura pe oun yoo ko awọn ọmọ ẹgbẹ jọ ni awọn idibo ti n bọ, ti oun yoo si sọ fun wọn pe wọn ko gbọdọ dibo fun  awọn oludije ti ko ni ilana eto ti o han gbangba lori atunṣe eto ilera  orilẹ-ede.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button