Take a fresh look at your lifestyle.
Democracy

Nàìjíríà le jẹ́kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó dára jù lọ – Ọ̀sínbàjò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 64

Igbákejì Ààrẹ Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Ọ̀sínbàjò sọ pé Nàìjíríà ní gbogbo ohun tí ó gbà láti di ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára jù,ó rọ àwọn ará ìlú láti yan olórí tí ó dára jùlọ fún orílẹ̀-èdè ní ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2023.

Ọjọgbọn Ọsinbajo sọ eyi ni Ọjọbọ, nigba ti o n ṣepade  pẹlu awọn alabaṣepọ ati awọn aṣoju ẹgbẹ All Progressive Congress (APC), ni Ipinlẹ Kano, ti o si tẹsiwaju lori ifikunlukun rẹ jakejado orilẹ-ede.

Ni kutukutu owurọ ọjọ Iṣẹgun ni Ilu Abuja, Igbakeji Aarẹ gba ami ẹyẹ gẹgẹ bii  Alakoso tootọ ti Odun 2021 nibi apejọ Ọdọọdun iwe-iroyin Leadership ati ayeyẹ ami ẹyẹ  ti ọdun yii.

Ṣaaju ki o to lọ si ibi ipade  ibaraẹnisọrọ rẹ pẹlu awọn aṣoju APC ati awọn ti o nii ṣe ni Kano, Igbakeji Aarẹ duro ni ibi ti bugbamu ti ṣẹlẹ lowurọ ọjọ Iṣẹgun, ni agbegbe Sabon Gari, Ipinlẹ naa, lati kẹdun pẹlu idile  awọn olufaragba ati awọn eniyan  Ipinlẹ naa.

Leave A Reply

Your email address will not be published.