Take a fresh look at your lifestyle.

ASUP:Ilé-èkọ́ gíga iṣẹ́ ọwọ́ Násáráwá Darapọ̀ mọ́ ìyanṣẹlódì gbogbogbòò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 179

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ olùkọ́ni ilé-ẹ̀kọ́ gíga iṣẹ́-ọwọ (ASUP), Isa Mustapha Agwai, Láfíà, ìpínlẹ̀ Násáráwá, Nàìjíríà  ti darapọ̀ mọ́ ìkìlọ̀ ìdaṣẹ́sílẹ̀  ọlọ́sẹ̀ méjì tí ẹgbẹ́ náà  kéde jákèjádò orílẹ̀-èdè lórí bíbèèrè fún ìgbé ayé ìrọ̀rùn àwọn ọmọ ẹgbẹ́.

Alaga ẹgbẹ ile-ẹkọ naa, Ọgbẹni Silvester Aku, lo sọrọ naa lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni Lafia, olu-ilu ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bi o ti sọ, idaṣẹsilẹ naa wa ni ibamu pẹlu aṣẹ lati olu ile-iṣẹ wọn lori ipinnu ti o waye nibi ipade Igbimọ Alaṣẹ apapọ ẹgbẹ ti o waye ni ilu Abuja.

Ọgbẹni Aku sọ pe igbese naa ti o di eyi ti ko ṣee yẹ,waye nitori ikuna  Ijọba apapọ lati ṣe awọn nnkan ti wọn beere gẹgẹ bi o ṣe  wa ninu iwe adehun  ti o fowo si ni ọdun 2021.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button