Àpèjọ Àgbáyé Lórí Ìgbógunti fífọmọ ṣòwò ẹrú bẹ̀rẹ̀ Ní South Africa
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Bí Àpèjọ Káríayé Karùn-ún lórí Ìgbógunti fífọmọ ṣòwò ẹrú ti bẹ̀rẹ̀ ní Durban,orílẹ̀-èdè South Africa, Àjo Àgbáyé Àwọn òṣìṣẹ́, ILO sọ pé ó ju ọgọ́jọ mílíọ̀nù àwọn ọmọdé tí wọ́n fi ń ṣòwò ẹrú.
Gẹgẹ bi ILO ṣe sọ,eyi tọka si pe o fẹrẹ jẹ ọkan ninu mẹwa gbogbo awọn ọmọde agbaye ni wọn fi n ṣowo ẹru.
Nitorina apejọ naa n pe fun igbese to “lagbara” ni kiakia lati koju bi lilo awọn ọmọde fi ṣowo ẹru ṣe n pọ si.
Nigbati o nsoro ni ibẹrẹ ijiroro ọlọsẹ kan naa, Aarẹ orilẹ-ede South Africa Cyril Ramaphosa, pe awọn aṣoju lati pinnu lati mu ohun ti o pe ni “ iṣe takuntakun” lati mu ki iyatọ deba igbesi aye awọn ọmọde.