Take a fresh look at your lifestyle.
Democracy

Olórí Orílẹ̀-èdè Nàíjiríà bu ẹnu àtẹ́ lu pípa ọmọ ilé ìwé kan ní ìpínlẹ̀ sokoto lọ́nà àìtọ́

0 69

Ààrẹ Muhammadu Buhari Bu ẹnu àtẹ́ lu iwa ibi tí àwọn jàndùkú ṣe ní ìpínlẹ̀ Sokoto, èyí tí ó yọrí sí ìwà ipá, bíba dúkìá jẹ́ àti pípa ọmọ ilé ẹ̀kọ́  Shehu Shagari College of Education, Sokoto,tí orúkọ rẹ̀ njé Deborah Samuel, lẹ́yìn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàń wípé ósọ̀rọ̀ lòdì sí Muhammad. (SAW), Ànábì Islam ní Ọjọ́bọ̀.

Ààrẹ Buhari sọ pé ìròyin pípa ọmọbìrin náà nípasẹ̀ àwọn ọmọ ilé-ìwé akẹgbẹ́ rẹẹ̀ jẹ́ ohun tí a gbọdọ̀ kọbi ara sí ní kíá kíá àtipé wọn kò gbọdọ̀ ṣe ojúṣàájú nínu ìwádìí lóri gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣaájú àti lákòkóò ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa ń wàásù pé kì í ṣe onígbàgbọ́ ló máa ṣèdájọ́ ìwà elòmíràn. A gbọ́dọ̀ yọ̀n dàa fún aláṣẹ tí a yàn láti bójú tó irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dìde.

Ààrẹ bá ìdílé ọmọ ilé-ìwé tí ó kú kẹ́dùn wọ́n sì gbàdúrà fún àwọn tí ó farapa pé kí Olúwa mú wọn láradá.

 

Ọláyinká Akíntọ́lá

Leave A Reply

Your email address will not be published.