Take a fresh look at your lifestyle.
Democracy

Ọwọ́ Ajọ EFCC tẹ afurasí oníjibìtì ori ẹ̀rọ ayélujára mẹ́tàlélógún nílùú Ìbàdàn

0 72

Ajọ to n gbogun ti sise owo ilu kumo-kumo, (EFCC) ekun ti Ibadan ti mu awon afurasi onijibiti ori ẹrọ ayelujara metalelogun (23) ni ilu Ibadan ti i se olu ilu ipinle Oyo ni ekun gusu iwo oorun orile ede Naijiria.

 

Gege bi ọga ẹka iroyin ati ikede ajọ EFCC, Wilson Uwajaren se salaye, pe mẹrindinlogun (16) ninu awọn afurasi ọhun ni wọn fi oniruuru ẹ̀sùn jibiti ori ẹrọ ayelujara kan latari awọn ohun ti wọn ka mọ wọn lọ́wọ́ lori ẹrọ alagbeka wọn ati awọn nnkan miran ti wọn ri gba lọwọ wọn, nigba ti isẹ́ iwadii si n tesiwaju lori awọn meje to ku.
O wa salaye pe gbogbo awọn afurasi wọnyi ni yoo foju ba Ile ẹjọ́ ni kete ti isẹ iwadii ba ti pari.

Awọn afurasi wọnyi ni ajọ EFCC gbamu ni ọjọ kejila osu yii ni agbegbe Apata, Jericho ati Ire Akari Estate ni ilu Ibadan. Awọn ohun ti wọn ri gba lọwọ wọn ni ọkọ ayọkẹlẹ  (7), ẹrọ alagbeka, ẹrọ agbélétan ti a mọ si (laptop) ati awon oniruuru iwe to tọka si isẹ jibiti ti wọn ń se.

 

Abiola Olowe
Ibadan

Leave A Reply

Your email address will not be published.