Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn Olùkọ́ Fáfitì lóri ìyanṣélódì.

0 25

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ẹgbẹ́ tó mójútó ètò ẹkọ orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n ro ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì fòpin sí ìyanṣélódì tó ń lọ lọ́wọ́ nítorí ire orílẹ̀-èdè Nàíjiríà.

Àwọn olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ọ̀sẹ̀ méjìlá mìíràn ní àfikún ìgbésẹ̀ wọn bí  ìdúnàdúrà mìíràn ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ yìí.

Ààrẹ náà tún rọ àwọn ọmọ ilé-ìwé ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ìlú Nàíjiríà láti ní sùrúù bí ìjọba ṣe ń gbìyànjú láti kojú àwọn ìṣòro tí ó wà nínú ètò ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti orílẹ̀-èdè Nàíjiríà.

 

Ọláyinká Akíntọ́lá

Leave A Reply

Your email address will not be published.