Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́lu ìwé òfin, àwọn ìwé òfin mẹ́ta tí ó ní èrò láti dẹ́kun owó kíkójẹ lónà àìtọ́, àti dáá àwọn tí ó ń kówó fún aẁọn oníjàgìdíjàgan/Ìlànà ìnáwó ní Nàíjiríà.
Àwọn ìwé-òfin náà jẹ́: Nínáwó ní àìtọ́ (Ìdènà àti Ìdádúró) 2022, Jàgídíjàgan (Ìdènà àti Ìdádúró) 2022, àti àwọn Ìlànà ti arúfin (Ìgbapàdà àti Ìsàkóso) 2022.
Nígbàtí ó ńsọ̀rọ̀ ní ayẹyẹ ìbuwọ́lù kan ní Ìgbìmọ̀, Ilé-ìgbìmọ̀ Ìpínlẹ̀ Abuja, Ààrẹ ṣe àpéjúwe àwọn òfin náà bí ó ti wà ní ìbámu pẹ̀lu ìṣàkóso láti jagun ìbàjẹ́ àti àwọn iṣẹ́ ìnáwó tí kò tọ́, bákànnáà tí ó ṣe pàtàkì sí ètò ìṣàkóso ìjọba àti ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè Nàíjiríà.
Ọláyinká Akíntọ́lá.