Take a fresh look at your lifestyle.

À ń fé àtìlẹ́yìn ìlú òkèèrè nínú òṣèlú àwa obìnrin orílẹ̀-èdè Nàíjiríà – Ìyáàfin Aisha Buhari

0 78

Ìyáàfin Ààrẹ Nàíjiríà, Ìyáàfin Aisha Buhari, ti pe àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ aṣojú ní orílẹ̀-èdè Nàíjiríà, láti ríi dájú pé àwọn obìrin ní ipa nínú òṣèlú.

Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ ìyáàfin, èyí ti di dándàn nítorí ìwúlò àwọn obìrin nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè Nàíjiríà.

Ìyàwó Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàíjiríà tún ké sí àwọn aṣojú ìjọba láti pèse ìrànlọ́wọ́ fún àwon ìyàwó olórí ilè Áfíríkà, láti jẹ́ kí wọ́n le ṣe afárá kí wọ́n sì gba àlàáfíà dípo ogun.

Ìyáàfin Buhari ṣe ìfilọ́lẹ̀ yìí ní Abuja, olú-ìlú orílẹ̀-èdè Nàíjiríà, nígbàtí ó gbàlejò àwọn olórí obìnrin ti aṣojú ìjọba ìlú òkèèrè, Àwọn ilé-iṣẹ́ gbogbogbò àti àwọn ìyàwó asojú orílẹ̀-èdè Nàíjiríà sí àpèjẹ ní ilé ńlá orílẹ̀-èdè Nàíjiríà.

 

Ọláyinká Akíntọ́lá

Leave A Reply

Your email address will not be published.