Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ máá fi ẹ̀tọ́ wa dùnwá

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 23

Awọn oṣiṣẹ eto ilera nipinlẹ Abia ni ana fi ẹhonu wọn han latari owo oṣu mejila wọn ti wọn ko san, ti won si n banujẹ wi pe ijọba ipinlẹ naa ti sọ igbimọ naa di ibi ibanujẹ, irora, ati iku.

Awọn oṣiṣẹ Igbimọ iṣakoso ile-iwosan  Ipinlẹ Abia sọ eyi ni Umuahia ni ọjọ iṣẹgun, ọjọ kọkandin-logun, Oṣu Kẹrin, lakoko ifẹhonuhan.

Àwọn òṣìṣẹ́ náà halẹ̀ mọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀, Okezie Ikpeazu, àti ìjọba ìpínlẹ̀ náà lati gbe wọn lọ sí ilé ẹjọ́, àti síwájú ojúbọ kan tí ó burú jàì kan ní ìpínlẹ̀ Anambra.

Awọn oṣiṣẹ naa  di opopona Aba ti o kunju ti wọn si n yira mọlẹ  lopona,bẹẹ naa si ni wọn  n ke pe ki Ọlọrun ko ṣaanu awọn.

Alága ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìṣègùn àti ìlera ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ẹ̀ka HMB, Mary Wokoma, sọ ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn nígbà tí ìfẹ̀hónú náà bẹ̀rẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ náà rọ àwọn òṣìṣẹ́ náà pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìdánilójú láti sanwó wọn láàárín ọ̀sẹ̀ méjì.

Leave A Reply

Your email address will not be published.