Aarẹ orilẹ ede Naijiria Muhammadu Buhari ti rọ awọn ile igbimọ aṣofin ile Afirika lati ṣe ifowosowopo pẹlu awọn adari, adajọ, aladani ati awọn ara ilu ni awọn orilẹ-ede wọn lati ri si idagbasoke to muna doko ni ilẹ Afrika lẹhin ajakaye-arun COVID-19.
Ipe naa wa ninu ọrọ rẹ ni apejọ awọn agbọrọsọ ati awọn olori ile-igbimọ ile Afirika ni Abuja, olu-ilu orilẹ-ede naa.