Take a fresh look at your lifestyle.

FAO: Iye Owó orí Oúnjẹ Àgbáyé wálẹ̀ nínú Oṣù Kẹrin

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 263

Àjọ àgbáyé fún Oúnjẹ àti Iṣẹ́-ọ̀gbìn, (FAO) sọ pé àwọn ìdíyelé ọjà àgbáyé  wálẹ̀ nínú Oṣù Kẹrin lẹ́yìn tí ọ̀wọ́n gógó gorí ọjà ní oṣù tí ó kọjá, èyí tí ó jẹ́ ìdarí nípasẹ̀ ìdínkù ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú àwọn ìdíyelé epo, ẹ̀fọ́ àti àwọn irúgbìn.

Atọka Iye Ounjẹ FAO ṣe aropin iwọn mejidin-lọgọjọ ati aabọ[ 158.5] ni Oṣu Kẹrin ọdun 2022,ti o si walẹ pelu ida kan ninu ọgọrun lati ọwọn gogo inu Oṣu Kẹta. Atọka naa, eyiti o tọpa awọn iyipada oṣooṣu ni awọn idiyele laarin orile-ede  agbọn awọn ọja ounjẹ to wọpọ,ti o fi ida ọgbọn ninu ọgọrun[ 29.8] wọn ju ti Oṣu Kẹrin ọdun 2021 lọ.

Atọka Iye ororo FAO walẹ pẹlu ida marun ati diẹ [5.7] ninu ọgọrun ni Oṣu Kẹrin, ti osi walẹ ni ilọpo mẹta ni  Oṣu Kẹta, aita epo ṣe mu owo ọpẹ walẹ, sunflower ati awọn epo soya. Aidaniloju nipa wiwa ọja okeere  lati jade ni Indonesia, olutaja epo ọpẹ ni agbaye, o n tunbọ mu idiyele walẹ laarin awọn orilẹ-ede.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button