Take a fresh look at your lifestyle.

ASUU tẹ̀síwájú pèlú ìyanṣẹ́lódì wọn

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 191

Ẹgbẹ́ òṣìṣé olùkọ́ni ti àwọn ìle-ẹ̀kọ́ gíga, ASUU ti fi oṣù mẹ́ta kún ìdaṣẹ́sílẹ̀ rẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe àpèjúwe gẹ́gẹ́ bíi ìkùnà ìjọba láti mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ.

Aarẹ ASUU, Emmanuel Osodeke fi idi rẹ mulẹ ni ọjọ aje, lakoko ti o n ba Voice of Nigeria sọrọ.

Osodeke fi ẹsun kan minisita fun iṣẹ ati igbanisiṣẹ fun bi wọn ṣe da owo oṣu  awọn ọmọ ẹgbẹ ASUU duro, ṣugbọn ti o fọwọsi sisanwo fun awọn ẹgbẹ miiran ni ile-ẹkọ giga, ti awọn naa si n yanṣẹlodi.

O sọ pe, ASUU n tẹsiwaju pẹlu  igbesẹ rẹ nitori pe ijọba ti ko kọbiara si ọrọ rẹ.

Ni ọsẹ to kọja ni Minisita ipinlẹ fun eto ẹkọ, Emeka Nwajuiba sọ pe ko bọgbọnmu fun awọn olukọni lati tẹsiwaju ni gbigba owo osu, laisi ṣiṣẹ.

Alaye siwaju laipẹ…

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button