Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ jọ̀wọ́, ẹ máa ti pápákọ̀ òfurufú pa-Senator Hadi Sirika

0 258

Lẹ́yìn tí àwọn òṣìṣé ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú ti orílẹ̀-èdè Nàíjiríà ti káàdí ètò láti ti ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú orílẹ̀-èdè Nàíjiríà paa lóóri iye owó epo ọkọ̀ òfurufú tó wú gọ́gọ́ lójijì, èyí tí a mọ̀ sí Jet A1, mínísítà tó sàmójútó fún ètò ọkọ̀ òfurufú, Alàgbà Hadi Sirika, ti fi dá wọn lójú pé ilé iṣẹ́ náà ń gba gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ ọ́ kàn  lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro náà.

Sẹ́nétọ̀ Sirika, ṣe àkíyèsi pé ilé-iṣẹ́ náà ṣe àníyàn púpọ̀ nípa àwọn ìṣòro tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú ń kojú ní wíwá epo ọkọ̀ òfurufú, èyítí ó ti yọrísí àwọn ìdíyelé tí ń pọ̀ si.

Èto títi ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú pa yóò bẹ̀rẹ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ kẹsàán, oṣù kaàrún, ọdún 2022.

 

Ọláyinká Akíntọ́lá

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button