Àìsàn tó ń yọ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Manchester United lẹ́nu kò ì tíì san rárá pẹ̀lú bí ikọ̀ Brighton & Holve Albion se nà wọ́n bí ẹní na asọ òkè. Àmì ayò mẹ́rin sí òdo ní wọ́n kó lé wọn lọ́wọ́.
Ipo kẹfa ni wọn fidi rẹmi si bayi, ti o si jẹ wipe irẹti wọn lati kopa ninu idije UEFA Champions League fun saa to n bọ ti fori sọnpọn.