Take a fresh look at your lifestyle.

Omi yalé: FCTA rọ àwọn olùgbé láti gbọ́ ìkìlọ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 29

Ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó ètò olú-ìlú,  (FCTA) ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn olùgbé láti gbọ́ ìkìlọ̀ tí ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó ń rísí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì , (FEMA) ńṣe fún wọn lásìkò, lẹ́yìn òjò tó rọ̀ lówùúrọ̀ kùtùkùtù ní Àbújá, olú ìlú Nàìjíríà.

Adari agba fun ajọ to n ri si pajawiri olu-ilu (FEMA), Alhaji Abbas Idriss, kede eyi ninu ọrọ kan ti Alukoro Ibaṣepọ Awujọ ile-iṣẹ naa, Nkechi Isa fọwọ si, ti o si fi han awọn oniroyin ni ilu Abuja.

Nigba to n sọrọ lori omiyale nla to sẹlẹ ni Dogongada ni Lokogoma, Damangaza ati Apo Dutse ni agbegbe Gudu, Alhaji Idriss so nipa eto lati di ona to ga lati Abule Games si opopona Papa ofurufu ati agbegbe  miran laarin olu-ilu lati le dena  omiyale ati akoyọ ẹmi ati oun ini.

Leave A Reply

Your email address will not be published.