Mozambique ń gbìmọ̀ ètò Òfin Láti Ṣàtúnṣe Àti láti gba owó-orí àwọn ilé ìjọsìn
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Mozambique ń gbìmọ̀ òfin tuntun kan tí yóò máa ṣàkóso ìgbòkègbodò àwọn ṣọ́ọ̀ṣì, tí wọn yóò fi le gbowó orí wọn, tí yóò sì pé kí wọ́n ní iye tí ó kéré jù igba ìfọwọ́sí láti lè forúkọ sílẹ̀.
Minisita Idajọ, T’olofin ati Ọran Ẹsin, Helena Kida, sọ pe itupalẹ ijọba kan ti ṣafihan “awọn ami ikilọ” bi awọn ile-ijọsin ṣe n pọ si.
Mozambique ni apapọ ẹgbẹ ẹsin ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́rún ti o forukọsile,ti wọn si fọwọsi sugbọn ọpọlọpọ tun wa ti wọn ko fọwọsi.
Igbimọ Kristiani ti Mozambique, CCM, faramọ ọpọlọpọ awọn pipese ofin ti wọn pinnu, o sọ pe o mọ pe ijọba fẹ “ṣe eto”.
Ipese lati gba owo-ori awọn ile ijọsin sibẹsibẹ n kọ awọn ile ijọsin lominu.