Wọ́n sún ọjọ́ Ṣíṣàyẹ̀wò àwọn olùdíje fún ipò ààrẹ PDP,Gómìnà síwájú – NWC
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìgbìmọ̀ àpapọ̀ ìṣiṣẹ́, (NWC) ẹgbẹ́ ti sún ọjọ́ ṣíṣàyẹ̀wò àwọn olùdíje fún ipò ààrẹ àti gómìnà láti ọjọ́ kẹta,oṣù karùn ún sí ọjọ́ kẹrin,oṣù karùn ún.
Bakannaa, igbimọ Alase apapọ ẹgbẹ People’s Democratic Party (PDP) naa ti sun ọjọ ipade wọn lati ọjọ karun,oṣu karun si ọjọ kẹwa,oṣu karun.
Alagba Samuel Anyanwu, Akọwe apapọ ẹgbẹ naa, lo fi eyi han ninu ọrọ rẹ kan.
Ninu alaye miiran Ọgbẹni Debo Ologunagba, Akowe apapọ olupolongo ẹgbẹ naa,sọ pe ayẹyẹ ọdun Eid-Fitr ni o fa isunsiwaju naa.
Gẹgẹ bi ẹgbẹ naa ṣe sọ, ọjọ naa bọsi ọjọ kannaa pẹlu idibo asoju ijọba ibilẹ, eyiti o kan gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ.
Ọgbẹni Anyanwu sọ pe ipade naa ti ko ba waye ni olu ile-iṣe ẹgbẹ, Wadata Plaza, Abuja, yoo waye ni bayi ni ọjọ kẹwaa,oṣu karun.
Leave a Reply