EU gbẹ́sẹ̀lé Epo orílè-èdè Rọ́síà Àti Àwọn ilé-iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Mẹ́ta
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àjọ ìṣọ̀kan yúróópù EU yóò gbẹ́sẹ̀lé gbígbéwọlé epo orílẹ̀-èdè Rọ́ssíà, àwọn ọjà tí wọ́n túnṣe àti àwọn olùgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ti ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́síà mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí apákan ìdíi ìjẹniníyà kẹfà lórí ogun Moscow ní Ukiréínì, adarí ẹgbẹ́ náà sọ ní Ọjọ́bọ̀.
Gẹgẹ bi Alakoso EU, Ursula von der Leyen, “A ko ni gba epo rọbi Rọsia laarin oṣu mẹfa ati awọn ọja ti a tunṣe ni opin ọdun.
Ursula von der Leyen, tun mẹnuba nipa awọn olugbohunsafẹfẹ ti ijọba mẹta ti o jẹ pe, “A ko ni gba wọn laaye lati pin akoonu wọn mọ ni EU, ni eyikeyi apẹrẹ tabi irukiru, boya lori okun, nipasẹ satẹlaiti, lori intanẹẹti tabi nipasẹ awọn ohun elo alagbeka. ”
O pe wọn ni amohunmaworan to jẹ agbẹnusọ irọ ati ete aarẹ Rọsia Vladimir Putin.
Leave a Reply