Al-Shabaab sọ pé òun ló wà nídìí ìkọlù apànìyàn tó ṣẹlẹ̀ ní Ibùdó AU ní Sòmálíà
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àwọn ajagun Al-Shabaab ti yabo ilé-iṣẹ́ ìṣọ̀kan Áfíríkà kan ní Sòmálíà pẹ̀lú ìbọn àti ibẹjadi ní ọjọ́ ìṣégun,ní èyí tí ó fa ìyìnbọn lura tí ó pa àwọn olùpèsè alààfíà Burundi.
Ọgágun ọmọ ogun Burundi kan ti o ga julọ sọ pe ọgbọn ọmọ ogun ni wọn pa ti awọn mejile-logun miiran si farapa,nigba ti ọpọlọpọ si sọnu.
Eleyi jẹ ikọlu akọkọ iru ẹ lori ibudo alafia lati igba ti AU Transition Mission ni Somalia (ATMIS) ti rọpo ologun ti tẹlẹ AMISOM ni ọjọ kinni, Oṣu Kẹrin.
Al-Shabaab, ti o ti n paniyan ni ijọba aringbungbun Somalia fun bii ọdun mẹwa kan sẹyin, sọ pe o ti gba iṣakoso ibudó naa ati pe oun ti pa awọn ọmọ ogun mẹ̀ta ĺe ńi àádọ́sán.
Leave a Reply