Mínísítà tó ń mójútó ilẹ̀ òkèrè ti ìlú Russia, Sergey Lavrov ti yọ́ọwí pé Moscow ò tíì setán láti dẹ́kun ogun jíjà ní àkókò ìrántí àṣeye wọn tí ń bọ̀.
Lavrov tún ti ṣàfihàn rẹẹ̀ pé ayẹyẹ Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ti Ìlú Moscow tí ń bọ̀ tí yóò wáyé ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù karùn-ún kì yóò ní ipa kankan lóri àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Ukraine.
Bakanna, Moscow sọ pé ẹgbẹ̀rún tó lé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹẹ̀ ti pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ogun náà. Bíotìlẹ́jẹ́pé Ukraine sọ pé àwọn àdánù Russia ló pọ̀ jù.
Ọlayínká Akíntọ́lá
Leave a Reply