Ẹgbé agbábọ̀ọ̀lù Real Madrid jáwé olúborí nínú ìdíje La liga nígbà tí wọ́n fi ẹgbé agbábọ̀ọ̀lù Espanyo ṣe eré ọwọ́ lóríi pápá pẹ̀lúu àmi àyò mẹ́rin sódo
Ẹgbé agbábọ̀ọ̀lù Madrid ò kúkú ní lò láti mi àwọ̀n kankan kí wọ́n tó leè jáwé olúborí, sùgbọ́n wọ́n fi àgbà han àwọn ẹgbé agbábọ̀ọ̀lù Espanyo nígbàtí Rodrygo kọ́kọ́ mi àwọ̀n ní ìsẹ́jú mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tí Benzema sí rìí dajúú pé wọ́n fi Espanyo sẹ̀sín lóri pápá.
Èyí sì jé ife márùndínlógójì tí ẹgbé agbábọ̀ọ̀lù Real Madrid ti ní, ní ìdíje yìí.
Ọláyinká Akíntọ́lá
Leave a Reply