Take a fresh look at your lifestyle.

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu fi Aláàfin Ọ̀yọ́ tó wàjà, Ọba Lamidi Adeyemi III wé “ọpọ́n ìmọ̀” Ilẹ̀ Yorùbá

0 66

Asiwaju Bola Tinubu ló sọ ọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ ní àsìkò tí wọ́n ṣe ádùrá ọjọ́ kẹjọ ní ìrántí ìpapòdà Aláàfin Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Adeyemi III. Ètò ọ̀hún ló wáyé ní Aganju tó wà ní Ààfin ìlú Ọ̀yọ́, ní ìpínlè Ọ̀yọ́ tó wà ní ẹkùn gúsù Iwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó tẹ̀ síwájú nínú ọ̀rọ rẹ̀ wípé Ọba Adeyemi III nífẹ̀ síí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní pàtàkì jùlọ ìtàn ẹ̀ya Yorùbá.

Ṣáájú àsìkò yìí ní ẹgbẹ́ onígbàgbọ́ (CAN), ẹ̀ka ti ìpínlè Ọ̀yọ́ tí Apostle Femi Akinyemiju jẹ́ Alága rẹ̀ gba gbogbo àwọn tó péjú níyànjú nínú Bíbélì mímọ́ nígbàtí ó rọ gbogbo lọ́ba-lọ́ba; àwọn Baálẹ̀; àti gbogbo àwọn tó di ipò ìjọba mú láti tún ilẹ̀ wọn tò kí ọlọ́jọ́ tó dé.

Bákan náà ní Asíwájú ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí láti ìlú Ilorin, Shehu Farooq Onikijipa rọ gbogbo àwọn tó péjú láti ṣe iṣẹ́ rere tí wọn bá gbàgbọ́ wípé ikú yóò mú àwọn náà lọ lọ́jọ́ kan gẹ́gẹ́ bí ikú ṣe mú Oba Lamidi Adeyemi III lọ.

Lára àwọn tó péjú síbi ádùrá ọ̀hún ni àwọn orí adé bíi Ọ̀ọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja II; Olúbàdàn Ilé Ìbàdàn, Ọba Lekan Balogun, Alli Okumade II; Olúwo ìlú Ìwó, Abdul-Azzez Akanbi, àwọn mìíràn tó tún péjú ni ìyálóde Ilé Yorùbá, Ìyálóde Alaba Lawson, Imaamu Àgbà Ilé Ọ̀yọ́, Alhaji Abdul-Ganiyu Ajokidero àti àwọn èyàn ńlá Míìràn láwùjọ.

Abiola Olowe
Ibadan.

Leave A Reply

Your email address will not be published.