Agbábọ́ọ́lù Orílẹ̀-èdè Egypt, Mohamed Salah gba àmì ẹ̀yẹ FWA Ọdún yìí
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ẹgbẹ́ òǹkọ̀wé bọ́ọ́lù àfẹsẹ̀gbá ti fún Agbábọ́ọ́lù àgbáyé, ọmọ orílẹ̀-èdè Egypt tí ó tún jẹ́ agbábọ́ọ́lù fún Liverpool, Mohamed Salah ti gba àmì ẹ̀yẹ ọkùnrin agbábọ́ọ́lù ọdún níbi ìdìbò ọdọọdún ti agbábọ́ọ́lù tí ó mọ̀ gbá jùlọ ní orílẹ̀-èdè England, èyí jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kejì tí Áfíríkà ń gba àmì-ẹ̀yẹ yìí .
Salah, ti o jawe olubori ni ọdun 2018, ni ibo mejidin-laadọta, niwaju agbabọọlu Kevin De Bruyne ti Manchester City ati agbabọọlu Declan Rice ti West Ham United, ti o gba ipo keji ati ikẹta ni sisẹntẹle.
Salah,ẹni ti o jẹ ọmọ Ọdun mọkandin-lọgbọn ti fẹsẹ gbọn bọọlu wọnu awọn ni igba ọgbọn ti o si tun ṣe iranlọwọ lẹẹmẹrinla ninu idije mẹrinle-logoji fun Liverpool ni akoko yii ati pe o tun jẹ opomulero ẹgbẹ Juergen Klopp.
Liverpool lo n tẹle Manchester City ninu idije Premier League ti oku idije marun un ko fi pari lọwọ bayii.
Leave a Reply