Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Eko Fọwọ́ sí Òfin Ìfẹ̀sùnkàn Ara-ìlú, gbígbógún ti Ìwà-ìbàjẹ́,jíjábọ̀ Iṣẹ́ ìlú.

0 322

Ilé gbimọ Aṣòfin Ipinlẹ Eko ti fọwọ si atunṣe ofin Àjọ to nii ṣe pẹlu Ifẹsunkan Ara-ilu, gbigbogun tí Iwa-ibajẹ ati jijajabọ iṣẹ ìlú tí wọn ṣe ni ọdun 2021, lẹyin tí wọn ka a nigba kẹta ninu gbọngan ile igbimọ aosfin.

Ilé gbimọ Aṣòfin Ipinlẹ naa ṣe atunṣe tẹlẹ si ofin yìí nigba ti wọn yí orúkọ òfin naa kuro ni “Òfin Àjọ Ifẹsunkan Ara ilu ati Igbogun tí Iwa-ibajẹ” si “Òfin Ajọ Ifẹsunkan Ara-ilu, Igbogun tí Iwa-ibajẹ ati Ijabọ iṣẹ ìlú ti ọdun 2021, lẹyin tí wọn ka a nigba kẹta ninu gbọngan Ile Igbimọ Aṣofin náà.

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ìpínlẹ̀ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa, ẹni ti Igbakeji rẹ, Aṣofin Wasiu Eshinlokun-Sanni ṣojú fun lo dárí eto idibò naa ti wọn fi ohun ṣọkan sọ ọ di ofin

Oludari Ile naa wa pa a láṣẹ fun Adele Akọwe-àgbà Ile naa lati fi ẹda ofin naa ṣowọ sì Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinle Eko lati fọwọ si, ko le di ofin-amulo ilu.

 

 

 

Lanre Lagada-Abayomi

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button