Take a fresh look at your lifestyle.

Àdánù ńlá ló sẹ lẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́: Ọmọọba Akeem Adeyẹmi

0 50

Ọmọọba Akeem Adéyẹmí tó s’ojú ẹkùn Ọ̀yọ́ ní Ilé ìgbìmọ̀ asòfin orílẹ̀ èdè Nàìjírìa ló so òrò yí di mímọ̀ ní Ààfin ní ìlú Ọ̀yọ́, ní ẹkùn gúsù Ìwọ òòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjírìa nígbàtí ó sàlàyé wípé Ọba Làmídì Adéyẹmí lll jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ tolórí tẹlẹ́mù Ọmọ ìlú Ọ̀yọ́ lọ́kàn.

Nínú ọ̀rọ rẹ̀, Ọmọọba Akeem Adéyẹmí sàlàyé wípé Ọba Làmídì Adéyẹmí lll wáà lára àwọn tí ó gbé àṣà àti ìṣe Ilẹ̀ Yorùbá lárugẹ, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èdè gẹ̀ẹ́sì náà rọ ọba alayé ọ̀hún lọ́rùn ní sísọ.

Lára àwọn ọmọ rẹ̀ nínú òṣèlú, Honourable Adesoji Ojoawo tí ó je Alága ìjọba ìbílẹ̀ Ìwọ òòrùn Ọ̀yọ́ àti Honourable Leke Oyatokun, tó s’ojú ẹkùn Afijio ní Ilé ìgbìmọ̀ asòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún 2015 sí 2019 sàlàyé wípé àdánù ńlá ni ìpapòdà Ọba Làmídì Adéyẹmí lll jẹ́ fún wọn. Wọ́n wá gbàá ládùráà kí Ọlọ́run tẹ́ ọba alayé òhún sí afẹ́fẹ́ rere.

 

Ní déédé agogo méjìlá ku ìsẹ́jú mẹ́fà ni wọ́n ṣe àdúrà ní Ìlànà ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí sááju kí àwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé tó se ètò yókù.

 

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Leave A Reply

Your email address will not be published.