Take a fresh look at your lifestyle.

ÌWA LÍLU ARA ẸNI: DANDAN NI ÀYẸ̀WÒ ÀÀRÙN ỌPỌLỌ -MÍNÍSÍTÀ

0 167

Àjọ tó sàmójútó ètò fún àwọn obìrin lórílẹ̀ èdè Nàìjírìa, Pauline Tallen  ti sọ pè, o ti di dandan láti ṣe àyẹ̀wò ààrùn ọpọlọ kí ètò ìgbeyàwó to leè wáyé ní orílẹ̀-èdè, Nàìjírìa

Pauline Tallen ṣọ ọ̀rọ̀ yìí ní Abuja, tó jẹ́ olú-ìlú orílẹ̀-èdè, lákòkóò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀  lóri àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń sẹlẹ̀ lóri ìwa lílu ara ẹni tí ó gbòdekan.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ,  ìwa-ipá tí ó dá lóri bi àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin ṣe ǹ lu ara wọn, ní èyí tó ń fa ikú àìtọ́jọ́ láwùjọ yìí, ní èyí tó sẹlẹ̀ ní à̀wọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn,fẹ́ ètò àmójútó àti ìgbésẹ̀ ní kíakía.

Ó tún késí àwọn ìyá láti kọ́ àwọn ọmọkùnrin kí wọ́n mọ ojúṣe wọn nínú ìgbéyàwó láìsí Ìbẹ̀rù kankan.

 

Ọláyinká Akíntọ́la

Leave A Reply

Your email address will not be published.