Take a fresh look at your lifestyle.

ALÁÀFIN ÌLÚ Ọ̀YỌ́, ỌBA LÀMÍDÌ ADÉYẸMÍ III TI WÀJÀ

0 558

Ọba Làmídì Adéyẹmí lll tí ó di olóògbé ní ilé ìwòsàn fáfitì Afe Babalola ní ìlú Ado-Ekiti, ní ìpínlè Ekiti ní ẹkùn gúsù iwọ̀ oòrùn orílè èdè Nàìjírìa, ni ìròyìn fi ìdí rẹẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti gbé ọba tó papòdà ọ̀hún lọ sí Agbonju ní ìlú Ọ̀yọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù yìí, níbi tí àkọ́bí rẹ̀ ọmọọba Tunde Adeyemi ti tẹ́wọ́ gbàá.

Ọba Làmídì Adéyẹmí lll ni wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹwàá ọdún 1938 (15/10/1938) tí ò sì gun orí àpèrè baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kọkànlá, ọdún 1970 (18/11/1970).

 

Abiola Olowe

Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button