Take a fresh look at your lifestyle.

Ipinlẹ Èkó ti ilé ìkọ́jàpamọ́ pa Lórí Títa mílííkì tó ti bàjẹ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 119

Àjọ tó ń dáàbò bo àwọn oníbárà ní ìpínlẹ̀ Èkó ti pàṣẹ láti ti ilé-ìtajà tí ó ń pín ọjà kan ní òpópónà Wilmer ní agbègbè Ìshẹ́ri-Òjòdú ní ìpínlẹ̀ náà, lórí títa wàrà tí kò dára mọ́.

Ilana naa waye lẹyin ti Alakoso Agba Gbogbogbo ti Ile-iṣẹ Idaabobo Awọn onibara ti Ipinlẹ Eko (LASCOPA), Afọlabi Solebo (Esq), darii ẹgbẹ agbofinro kan si ile-itaja ti n pinja, lẹyin ti fidio kan jade lori ayelujara ti o fi ọkunrin agbalagba kan ti o n ta wara naa fun awọn eniyan ti mọ han ni opopona Ibidun, ni agbegbe Ojuẹlẹgba ni ipinlẹ naa.

Solebo salaye pe, ọkunrin naa ṣalaye pe ile itaja ni Wilmer Street ni Isheri, Berger,ni ohun ti gba miliiki naa lakoko ti awọn agbofinro,Ago ọlọpa Area C ni Surulere fọrọwalẹnuwo.

Gẹgẹ bi ọga LASCOPA,wọn ti ti  ile-itaja pa lati da tita wara ti o lewu naa duro  ati ki wọn o si tun le gbaa kuro lọwọ awọn to ti raa lati majẹ ki awọn olugbe o lanfaani si wara ti o lewu fun ilera wọn.

Leave A Reply

Your email address will not be published.