Ẹ̀to Idìbò Ọdún 2023: “Àgbájọwọ́ La Fí N Sọ̀yà”, Ẹ̀yin Ọmọ Nàìjíríà, Ẹ Se Ara Yín Lósùsù Ọwọ̀
Olùdíje Ààrẹ lábẹ́ ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ òsèlú People’s Democratic Party (PDP), ẹni tí ó sì tún jẹ́ Gómìná Ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ọmọ Nàìjírìa láti ṣiṣẹ́ pọ̀ fún ìsọ̀kan orílẹ̀-èdè láì fi ti ìyàtọ̀ ẹgbẹ́ ṣe
Gómìnà Wike ló rawọ́ ẹ̀bẹ̀ lásìkò tó ṣe àbẹ̀wò sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Umar Ganduje ní ilé ìjọba, ìpínlẹ̀ Kano.
Ó sọ pé Nàíjírìa ń kojú àwọn ìpéníjà díẹ̀, àti pé ó nílò ìgbìyànjú àpapọ̀ láti borí wọn. Ní àfikún, gẹ́gẹ́ bi ènìyàn tí ó ní ìbáwí, ó sì kádìí rẹẹ̀ ńlẹ̀ pé òhún ṣetán láti darí orílẹ̀-èdè náà kúrò nínú àwọn ìpéníjà yìí pẹ̀lú àwọn ìrírí tí ó ní.
Leave a Reply