Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ jáwọ́ nínú dídábẹ́ fún àwọn ọmọbìnrin-Oluwakemi Olawoyin

0 95
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pẹ̀lú àjọsepọ̀ ajọ Hacey Health Initiative ló se àgbékalẹ̀ ìdánilẹ̀ẹ̀kọ́ fún awọn akọroyin ni ipinlẹ Ọ̀yọ́ lori ipa ti wọn le ko lati fi opin si ìdábẹ́ fun awọn ọmọbinrin (Female Genital Mutilation, FGM) eleyi ti o kun fun oniruuru ewu.
ìdánilẹ̀kọ̀ọ́ ohun to waye ni agbegbe Ikolaba ni ilu Ibadan,ipinlẹ Ọ̀yọ́ niẹekun gusu Iwọ oorun orilẹ ede Naijiria ni abilekọ Oluwakemi Olawoyin, ti o jẹ oludari (FGM Coordinator) ni Ile isẹ́ to n pese Eto Ilera Alabọde ni ipinlẹ Ọ̀yọ́ (Oyo State Primary Health Care Board), ti o tun jẹ ọkan lara awọn olùdánilẹ̀kọ̀ọ́ ti yanana ewu ti o ro mo ida’be fun omo obinrin.
Nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu ti o rọ̀ mọ́ ìdábẹ́ fun ọmọ obinrin ni o sokunfa bi ijọba ni elekajeka se n se idanileko lori ifopin si asa yi ti won si se agbekale ofin ti o lodi si, ninu eyi ti gbogbo awon ti o ba tapa si ofin ohun yoo fi oju wi ina ofin.
Abilekọ Olawoyin tun salaye ninu ọ̀rọ̀ pé àjọsọ ati akọsilẹ ti wa pe opin ni lati deba dida abẹ́ fún ọmọ obìnrin nígbà ti yóò ba fi di ọdún 2030.

 

 

Abiọla Ọlọwẹ

Ibadan

Leave A Reply

Your email address will not be published.