Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn afẹ̀hónúhàn Sri Lanka Bèèrè Ìdájọ́ Fún ìkọlù Ọjọ́ àjíǹde Krísítì Ọdún 2019

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 186

Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Sri Lanka ń fi ẹ̀hónúhàn láti bíi  ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn nítósí ọ́fíísì ààrẹ tí wọ́n sí ǹ bèèrè fún ìdájọ́ òdodo fún àwọn olùfaragbà ìkọlù aburú Ọjọ́ àjíǹde Kírísítì tí ó   ṣokùnfà ikú àwọn ọgbọ̀ndín-lọ́ọ̀dúnrún ènìyàn  ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn.

Awọn afẹhonuhan naa n beere lọwọ ijọba lati ṣe iwari awọn ti o wa nidii  ikọlu lori awọn ile ijọsin mẹta, Katoliki meji ati Pirotẹsitanti kan ti o waye pẹlu igbẹmi ara ẹni nigbakanna lakoko ayẹyẹ Ọjọ ajinde Kristi ni Oṣu Kẹrin, Ọjọ kọkanle-logun, Ọdun 2019.

Wọn tun kọlu Awọn ile itura oniriajo mẹta kan, ti wọn si pa awọn ajeji mejile-logoji lati awọn orilẹ-ede merinla.

Ni ọjọ aiku, awọn afehonuhan tan abẹla ti wọn si ṣe afihan awọn asia ati awọn kaadi iranti,ti wọn si n pe fun idajọ ododo fun awọn olufaragba awọn ikọlu Ọjọ ajinde Kristi

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button