Take a fresh look at your lifestyle.

Olalekan Ishọla Balogun di Olúbàdàn kejìlélógójì

0 321

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti fi idunnu rẹ han si olubadan tuntun, Ọba Olalekan Ishọla Balogun, Alli Okumade 2, ẹni ti o gba ọ̀pá àsẹ gẹgẹ bi Olubadan kejilelogoji lẹyin ọjọ́ Mejilelaadọrin ti olubadan ana, Oba Saliu Adetunji Ajeogungunniso 1 papòdà.

Eto yii lo waye ni Oke Mapo ni ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ni ẹkun gusu Iwọ oorun orilẹ ede Naijiria, ti awọn eekan ni tibu-tooro orilẹ ede Naijiria péjú lati yẹ́ Oba alaye ọhun si.

Gomina wa fi asiko ohun gba Kabiyesi ati awọn igbimo olubadan niyanju lati ri daju pe wọn fi idi ofin ti wọn fi n jẹ olubadan mulẹ.

 

Gomina wa gba ladura pe ki ade pẹ lori, ki bata pe lẹ́sẹ̀, ki irukẹrẹ di ọkini fun ọba Ọlalekan Ishọla Balogun Alli Okumade 2, ki igba re tu tolori telemu Ile Ibadan lara.

 

 

 

Abiola Olowe
Ibadan

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button