Aṣiwaju ,a-ji-ja-gbara fun idasilẹ orilẹ ede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ , ti a mọ si ,Sunday Igboho ni awọn alaṣẹ orilẹ ede Benin Republic ti fi silẹ ninu ahamọ ti wọn fi si.
Iroyin sọ pe ijọba orilẹ ede Benin fi Ajijagbara ọhun silẹ lọjọ Aje , ọjọ keje, osu kẹta ti a wa yii, fun awọn adari ikọ̀ Yoruba , ti a mọ si ,Ilana ọmọ Oodua agbaye, labẹ akoso ọjọgbọn Banji Akintoye ati ọjọgbọn Wale Adeniran.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ Ilana Omo Oodua , Maxwell Adeleye gbe jade , lati salaye pe bi wọn se fi Sunday Igboho silẹ jẹ aseyọri imọlẹ to bori okunkun.
Leave a Reply