Take a fresh look at your lifestyle.
Democracy

Gómìnà Seyi makinde se ìbẹ̀wọ̀ sí àwọn ẹbí olóògbé Alao Akala

0 111

Lẹyin  ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde se ibẹwo si opó ati idile olubadan, ọba Saliu Adetunji Ajeogungunniso 1 to waja, Gomina tun se ibẹwo ibani-kẹdun si opó ati idile Otunba Adebayo Alao Akala, ẹni ti o dagbere faye ni ẹni ọdun mọkanlelaadọrin (71) ni owurọ ọjọ́ kejila, osu yii. ọjọ kejila, osu kinni , ọdun 2022.

 

Nigba ti gomina n ba awon opo ati ẹbi oloogbe naa sọrọ ni Ilẹ rẹ to wa ni ‘Opadoyin Logde’, ni agbegbe Randa ni ilu Ogbomọsọ, ipinlẹ Ọyọ ni ẹkun gusu iwọ oorun orilẹ ede Naijiria, o wa gba wọn niyanju lati dupẹ lọwọ Ọlọrun nitori oloogbe Alao Akala gbe igbe aye rere.

 

Bakan naa ni gomina se alaye pe, oloogbe Alao Akala je ẹni ti o ni ifẹ ipinlẹ Ọyọ lọkan ti o si sa ipa rẹ lati ri pe ipinlẹ Ọyọ tẹsiwaju.

Nigba ti o n feesi, ọmọ oloogbe Ọlamiju Alao-Akala fi ẹmi imoore han si gomina ati gbogbo awọn to kọwọọrin pẹlu rẹ fun ibẹwo ibanikẹdun wọn si ẹbi ati idile oloogbe Alao Akala.

 

Lara awọn to tẹle gomina Seyi Makinde ni: Akọwe ijọba, Abileko Olubamiwo Adeọsun; Olori osisẹ gomina, Hon. Segun Ogunwuyi; Olori osisẹ ijẹba, Alhaja Amidat Agboọla ati awẹn eekan miran.

 

Abiola Olowe
Ibadan

Leave A Reply

Your email address will not be published.