Take a fresh look at your lifestyle.
Democracy

A ó fadé orí wa sílẹ̀ láti tẹ̀lé ìlànà jíjẹ Olúbàdàn:Ìgbìmọ̀ Olúbàdàn,àwọn olóyè

0 99

Ni ibamu pẹlu ipinnu gomina Seyi Makinde lati tẹle Ilana bi wọn se n jẹ ọba niluu Ibadan ni igbimọ Olubadan ati awọn oloye eleyii ti gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ, oloogbe Abiola Ajimobi gbega si ipo ori-ade se pe ipade lati fenu ko lati faramọ mọ  pe awọn yoo fi ade ori wọn  silẹ ,ki wọn si pada si ipo ‘oloye’ eleyii ti wọn ti wa tẹle.

Ipade ọhun lo waye ni aafin Olubadan Ilẹ Ibadan ni Oja’ba, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ni ẹkun gusu iwọ oorun orilẹ ede Naijiria.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe, Osi Balogun (Agba-Oye Tajudeen Ajibola), ẹni ti o gba ẹnu igbimọ yooku sọrọ jẹ ki o di mimọ pe awọn gẹgẹ bi afọbajẹ ti fẹnuko pẹlu gomina Seyi Makinde lati pada si ipo ‘oloye’ eleyi ti wọn wa saaju ki gomina Ajimọbi to gbe wọn ga si ipo ‘ori-ade’. O wa fi kun un pe, ilana lati jẹ ‘Olubadan’ si wa bi o ti wa latẹyin wa.

lara awọn ti o wa nibi  ipade ọhun ni: Balogun Ilẹ Ibadan (Agba-Oye, Owolabi Olakulehin); ọtun Balogun (Agba-Oye Tajudeen Ajibola); Osi Balogun (Agba-Oye Lateef Adebimpe); Ashipa Balogun (Agba-Oye Kọla Agboọla; Ashipa Olubadan (Agba-Oye Eddy Oyewole) ati Ẹẹkarun Olubadan (Agba-Oye Hamidu Ajibade). Bakan naa ,ni a ri awọn ori -ade miran ati awọn Mogaji agbo’le ti o to mẹẹdogun niye.

 

 

Abiola Olowe
Ibadan.

Leave A Reply

Your email address will not be published.