Take a fresh look at your lifestyle.

Iṣuna-owo ọdun 2022: Ipinlẹ Eko yoo so eso rere- Ọbasa

0 257

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti fi da awọn eniyan Ipinlẹ Eko loju pe eto Iṣuna-owo ọdun 2022 ti Gomina Ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu gbe wa siwaju Ile Igbimọ Aṣofin naa yoo mu igberu ba awọn olugbe ipinlẹ yii.
Aṣofin Ọbasa sọrọ idaniloju yii nibi ayẹyẹ iṣide ipade apero ọlọjọ mẹta lori eto iṣuna owo naa, ti wọn pe ni “Wiwa ojutu si awọn ohun to ṣe pataki leyin laasigbo arun COVID-19”.
Oludari Ile Igbimọ Aṣofin naa, ẹni ti igbakeji rẹ, Aṣofin Wasiu Eshinlokun-Sanni soju fun, woye pe awọn iṣuna owo ni Ipinlẹ Eko ti n ni ipa rere laarin ilu latari awọn olori rere ti ilu n yan sipo.
O ni ipade apero yii yoo jẹ ki awọn to fe ṣagbeyewo iṣuna-owo ilu yii ni oye kikun nipa ilana iṣiṣẹ ijọba, ati lati le fọwọsowọpọ pẹlu ẹka amuṣẹṣe ijọba fun aṣeyọri eyi. O ni:
“Eleyii yoo le seranwo lat je ki a ni oye nipa ilana isise ijoba ipinle yii lojuna ati mu igberu ba ipinle yii ati awon olugbe re. Bakan naa yoo le je ki a ni oye awon akoonu eto isuna-owo naa daradara.” O wa ro awon akopa naa lati ri i daju pe olukuluku lo kopa tire gege bo se ye.
Ninu ọrọ ikini-kaabọ rẹ, Adele Akọwe-agba Ile Aṣofin naa, Ọgbẹni Ọlalekan Ọnafẹkọ ki awọn akopa gbogbo, fun ilakaka wọn lati mu igberu ba Ipinlẹ Eko. O ni gbogbo ijiroro wọn nibi ipade yii yoo jẹ ipa pataki ti Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ko lori aṣeyori eto Iṣuna-owo ọdun 2022 yii.
Lara awọn aṣofin Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko to sọrọ nibi ayẹyẹ iṣide ipade apero naa tẹnu mọ ọn pe erongba awọn ni lati tubọ kọ ẹkọ si nibi apero naa, ti atubọtan rẹ yoo le mu Ipinlẹ Eko debi giga, ti awon yooku yoo le wo awokọṣe rẹ.

Leave A Reply

Your email address will not be published.