Ile-isẹ aarẹ ti ni ahesọ ati ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni iroyin ti awọn kan n gbe jade pe , ijọba apapọ ti ni ki wọn da awọn alakoso ile-isẹ to n mojuto iná mọna-mọna to wa niluu Abuja, iyẹn Abuja Electricity Distribution Company AEDC duro.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun aarẹ Muhammadu Buhari , Garba Shehu gbe jade lo ti sọ pe :
“Àhesọ ati ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni iroyin ti awọn kan n gbe jade pe , aarẹ Muhammadu Buhari ti pasẹ pe ki wọn da awọn alakoso ile-isẹ to n mojuto iná mọna-mọna to wa niluu Abuja, iyẹn Abuja Electricity Distribution Company AEDC duro .
“Irọ patapa ni eleyii nitori pe ijọba apapọ ti fa ile-isẹ mọna-mọna le awọn ile-isẹ aladaani lọwọ lati maa sakoso rẹ̀ lati ọdún 2013. Nitori naa, ijọba apapọ ko lẹtọọ lati da alakoso naa duro“