Take a fresh look at your lifestyle.

COVID-19: Àwọn ènìyàn mẹ́tàdínláàdọ́ta míràn tún ti ní àrùn korona

0 167

Ajọ to n mojuto ajakalẹ arun lorilẹ ede Naijria tun ti kede pe awọn eniyan mẹ́tàdínláàdọ́ta miran tun ti ni arun COVID-19.

Ajọ NCDC lo kede eyi lori itakun ẹrọ  Facebook wọn lọjo Ẹti pe awọn ipinlẹ ti arun ọhun ti jẹyọ ni  “Plateau- mẹrindinlogun(16), FCT- mẹ́jọ(8), Rivers-mẹ́jọ(8), Gombe-mẹ́rin(4), Kaduna-mẹ́rin(4), Edo-mẹ́ta(3), Kano-mẹ́ta(3), Bauchi-ọkan(1).”

Ni bayii, apapọ iye awọn to ni arun COVID-19 ti jẹ́ ẹgbàájì-le-ni-ọ̀kẹ́-mẹ́wáá-abọ-le-ni-mẹ́ta-din-ni-okòó-le-lọ́ọ̀dúnrún  (214,317) nigba ti iye awọn to ti gba iwosan si jẹ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin-le-ni-ọ̀kẹ́-mẹ̀wá-le-ni-mẹ́ta-din-ni-ọ́ta-lelọ́ọ̀dúnrún (207,357) , nigba ti awọn eniyan ti iye wọn jẹ èjì-le-ni-okòó-din-ni-ẹgbẹ́ẹ́ẹdógún (2,978) ti padanu ẹmi wọn .

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.