Take a fresh look at your lifestyle.

Sanwo-Olu Ṣagbekalẹ Iṣuna-owo 2022 siwaju Ile Aṣofin Eko

0 313

Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinlẹ Eko ti ṣagbekale Tirilioonu kan, ọọdunrun le ni aadorun-din meji Biliọnu, igba le laadọrun-din-marun Miliọnu, ẹgbẹrun lọna ọta-le-ni-irinwo-din-ookan ati aadọwa-din-mẹwa owo naira pẹlu kọbọ mọkanlelaadọta (N1,388,285,459,990.51) gege bi abadofin owo-iṣuna ọdun 2022 fun Ipinlẹ Eko siwaju Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko. Eleyii to pe akori re ni, “Eto iṣuna-owo Isọdọtun” lo fi Biliọnu lọna meji-le- ọgbọn-le-ni-igba ju ti ọdun 2021 lọ.
Eto iṣuna-owo ọdun 2022 yii ni owo-na fun iṣẹ akanṣe ilu rẹ jẹ Biliọnu okoo-le-lẹgbẹrin ati mẹta, aadọta le ni-ọọdunrun ati ookan miliọnu, ẹgbẹrun lọna ọgọfa-le-mejọ ati mẹrinlelọgọrun-un owo naira pẹlu kọbọ mẹwaa (N823,351,123,104.10), ti owo-na fun inawo atigbadegba rẹ jẹ Biliọnu lọna ọta-le-leedegbeta ati merin, ọgbọn-le-leedegbewa ati merin miliọnu, ẹgbẹrun lọna ọgbọn-le-lọọdunrun ati ookan, ati ọgọsan le ni mẹrin-din-laadọrun pẹlu kọbọ mọkan-le-logoji (N564,934,331,886.41)
Gẹgẹ bi Gomina ṣe fi mulẹ gbogbo iye owo ti ijọba n foju sun ti yoo wọle lati na fun isuna-owo ọdun 2022 yii jẹ Tiriliọnu kan, Bilionu lọna marun-din-logoje Miliọnu ọgọjọ-din-ookan, egberun lọna meji-le-laadọrun ati okoo-le-lẹgbẹrin ati meji owo naira pelu ọgbọn kọbọ (N1,135,159,092,822.30), ti ijọba yoo pa wọle labẹle ati eyi ti ijọba apapọ yoo fun won. Ipele ọrọ-aje ati ẹka ijọba ni Gomina Sanwo-olu yan-na-an-na isuna-owo wọn lọkọọkan sinu abadofin naa.
Gomina Sanwo-Olu sọ pe owo yooku ti wọn yoo na sori isuna-owo naa yoo wa lati awọn eto ẹyawo labẹle ati lati ilẹ okeeere. Pẹlu igboya pe, eto iṣuna-owo ọdun 2020 yii yoo sọ igba dọtun, bi a se n bọ lọwọ ipalara arun Covid-19 bayii.
Ninu ọrọ rẹ, Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ajayi Ọbasa ro Gomina lati tubo siṣẹ lojuna ati jẹ ki awọn ara ilu gbogbo jẹ ere ijọba tiwantiwa ni ipinle yii. O wa gboriyin fun aṣeyori takutakun Gomina naa.
Oludari Ile naa tun pe ijọba apapo labẹ Aarẹ Mohammadu Buhari lati ṣatunṣe si ọrọ-aje orilẹ-ede yii lati le tubọ ṣadinkun airiṣẹṣe lorile-ede yii.
Aṣofin Ọbasa tun dupẹ lọwọ Ile Igbimọ Aṣofin naa fun awọn ipinnu to n tu ara ilu lara ti wọn n ṣe, ati atilẹyin wọn fun Gomina lati le ṣe awọn ohun ti awọn ara ilu n fẹ.
O ni eleyii ti so eso rere ninu awọn iṣẹ ijọba ipinlẹ yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button