Take a fresh look at your lifestyle.

ITTF Yan Ọmọ Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà , Wahid Oshodi Gẹ́gẹ́ Bí Igbákejì Alákoso

0 176

Wahid Enitan Oshodi ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni a ti yàn gẹ́gẹ́ bí Igbákejì Alákoso ti àjọ àgbáyé agbabolù orí tábìlì (ITTF); ní ọjọ́ kerinlelogun, oṣù kọkọnla; ní ìlú Texas, orílẹ̀-èdè Amerika.

Ọgbẹni Oshodi ni yoo jẹ ọmọ Niajiria keji ti a dibo yan ninu ajọ agbaye yii. Yoo si sisẹ pelu oludari meje miiran ninu ajọ na.

Bakan naa ni ọmọ orílẹ̀-èdè Egypt, Ọgbẹni Alaa Meshref jawe olubori ninu eto idibo naa; leyi to jẹ wipe igba akoko re ti omo ilẹ afrika meji yoo jawe olubori ninu idibo si ipo oludari ajọ naa.

Awọn ti wọn tun dibo yan ni Graham Symons lati orílẹ̀-èdè Australia, Alaor Azevedo lati orílẹ̀-èdè Brazil, Liu Guoliang lati orílẹ̀-èdè China, Roland Natran lati orílẹ̀-èdè Hungary, Masahiro Maehara lati orílẹ̀-èdè Japan ati Khalil Al-Mohannadi lati orílẹ̀-èdè Qatar.

 

Tolulope Akinseye

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.